Taiwo Akinrefon – Three In One

Taiwo Akinrefon, a multi-talented music minister, composer and song writer Comes Through With A New Single Titled; Three In One 
The song “Three In One” is a song that talks about the mightiness and the uniqueness of the Trinity. I.e God the father, God the Son and God the Holy Spirit.
Download & Be Blessed

DOWNLOAD MP3 

ABOUT MUSIC ARTIST

Taiwo Akinrefon is a multi-talented music minister, she’s a composer, song writer, a broadcast Journalist and a chanter.
She started singing at a tender age when she had the opportunity to join the choir unit of her Church. She’s one of the instruments that the Lord is using to populate the kingdom of God through soul lifting songs. She’s one of the gospel artistes whose song is healthy, quality driven and edible for spirit.
She holds a Bachelor of Arts in English Language from the prestigious university, Obafemi Awolowo University, Ile-Ife.
Based on her singing prowess as a song writer, She has many songs to her name. Her first released single is titled “Living Water” a song that talks about Jesus being the Living Water that quenches humans’ thirst, while “Ipọnju rẹ fẹ́rẹ̀” (Your affliction is Light) is her second song, a song that gives hope to hopeless people. In addition, “Promise Keeper” is another masterpiece from her that is trending on various digital and social media platforms as we speak.
 She also has an album to her name which she titled “Three In One. “Three In One”, a song that talks about the uniqueness and supremacy of the Trinity i.e God the father, God the son and God the Holy Spirit while “More Than Enough” is her latest release.
Connect:
Facebook: Taiwo Akinrefon
Instagram: iamtaiwoakinrefon
X(Twitter) Taiwo Akinrefon
TikTok: Taiwo Akinrefon
THREE IN ONE LYRICS
Lead: Three In one, I magnify your names, Mẹtalọkan
Mo f’ori balẹ, Unchangeable changers, oba mẹta ninu afinkan
Titi aye lẹo ma wa Ijọba yin konipekun.
Chorus:  Three In one, I magnify your names, Mẹtalọkan
Mo f’ori balẹ, Unchangeable changers, oba mẹta ninu afin kan
Titi aye lẹo ma wa Ijọba yin konipekun.
Verse 1! Eni mẹta to f’imo s’okan, t’oun dari aye ati ọrun,
Eti wa kato da aye, at’oun gbogbo t’oun bẹ ninu wọn
Ijọba kan lẹyin mẹtẹta n dari sibẹ, ọtọọtọ lẹ pín ṣẹ
Ninu afin kan lẹyin mẹtẹta tin jọba aditu lẹjẹ.
Chorus:  Ẹjọba ẹjọba , ẹjọba titi aye o, ẹjọba ẹjọba , ẹjọba oo, ẹjọba titi.
2ce
Verse 2. Baba ọmọ ati ẹmimimọ tẹni kankan ko mọn pilẹ wọn, ao morisun yin, amọ eyin lẹj’orisun f’ohun gbogbo, kosa kọ silẹ pọmọ lagbaja niyin o, ijinlẹ lẹjẹ
Chorus:  Ẹjọba ẹjọba , ẹjọba titi aye o, ẹjọba ẹjọba , ẹjọba oo, ẹjọba titi.
Bridge: In Christendom, a gbagbọ pe ọlọrun meta ninu ọkan ṣoṣo ni a un sìn
Ọlọrun baba, ọlọrun ọmọ, béè l’ọlọrun ẹmimimọ pẹlu e, igbimọ meta niwọn, wọn si n sise ni ijoba kan, bẹẹni afojusun kan ni won ni. O maun pamilerin ti awọn ti kii se elesin wa ba so pe eniyan mẹta lan sin, pe nje o seese ki ẹnikan sin ọlọrun meta po leekan soso.
Aditu leyi jẹ
Gẹgẹbi a se mọn pe ohun mẹta lo parapò to gbé eniyan ro, ẹmi, omi ati ẹjẹ ti won ṣi n sise ninu ara eniyan kan, omi o le ṣiṣe ẹjẹ, ẹjẹ o de le gba Ise omi se.
Bẹẹ na lose ri ninu ijọ ọlọrun.
Awọn meta loun jẹri ni orun; baba, Ọ̀rọ̀ tii se Jesu ati ẹmimimọ.
Ti a ba ka iwe Jòhánù Kinni, orí ikarun, bẹrẹ láti ẹsẹ ikefa ṣí ikesan, o sàlàyé e nibẹ.
Awọn mẹtẹta yi, ọkan ṣoṣo niwọn, Ise won yato, bẹẹ si ni abuda wọn ko báramu, sibẹ afojusun kan ni wọn ni. Ninu ijoba kan ṣoṣo naa ni, eleyi tiise ijọba ọlọrun. Nnkan t’awa se nibi lonii, oun ni lati so nípa titobi awọn mẹtẹta yi, nitori laisi awọn mẹtẹta yi ninu ayé eniyan, iru aye bee kolee ni itumọ.
Iwalaye awọn mẹtẹta yi, o un sise agbara.
Halleluyah!
Ọlọrun Baba
Call: Ọlọrun baba mogbede
Response: Mo gb’oriki d’ọdọ rẹ!
Call: Ẹni Ibẹru ni gbogbo agbaye
Response: To ba un binu talo le duro?
Call: Se bi wọ ni Tetragrammaton, lede Heberu
Response: Itumọ ni Yahweh
All: Lati igba atijọ ni atifi idi  itẹ rẹ kalẹ, iyin rẹ de opin aye o, ọwọ ọtun rẹ kun fun ododo
Chorus: Ẹjọba, ẹjọba, ẹjọba o, ẹjọba titi.
(Repeat chorus any time the lead sings)
Lead1:  Iwọ kọ ni ọlọrun ni ọrun ati ni gbogbo agbaye, ti oun se ijọba lori gbogbo awọn orilẹ-ède, ọwọ rẹ ni agbara ati ipa wa láéláé o
Ti enikeji ko lee ko loju.
Lead 2. Iwo ti ofi omi se iti igi aja iyẹwu rẹ o, iwo ti oun rin lori apa iyẹ afẹfẹ, Ose efuufu ni onse rẹ, ọlọrun, ọwọ ina ni iransẹ rẹ o jọba.
Lead 3. Iwọ ti o wọn omi ni koto owo rẹ tiosi fi ika wọn orun iwo ni moun ki, Oluwa, iwo ti ofi iwọn wọn awọn oke nla, kose ni taale fi ọ we o kosoun talefi sakawe rẹ.
Lead 4. Ẹlẹdaa gbogbo ipẹkun aye
Iwọ kìí saarẹ bẹẹni amodi kii mun ọ, kaka bẹẹ otun n fi agbara fún awọn ti ko ni ipa o, ẹjọba titi o.
Lead5. Oun bomirin awọn oke latinu iyẹwu rẹ wa, ere ise ọwọ rẹ tẹ araye lọrùn o, omu koríko dagba fun ẹran ati ewebẹ fun ilo eniyan laye.
Lead 6 : O da osupa fun akoko ti rẹ, orun mọn akoko ti yoo wọ, Oluwa, Iṣẹ ọwọ rẹ ti pọ to o, ninu ọgbọn n’iwọ ṣe gbogbo won, ẹjọba titi o.
Lead 7: Ogba awọn omi okun bi enipe okiti kan, o to ibu jọ ni ile iṣura,
Iwọ ti o jọba inu okun, orun ni tirẹ aye pẹlu ti ẹ ni
Otito ati idajọ ni ibujoko itẹ rẹ, ẹjọba Oluwa.
Chorus: Ẹjọba, ẹjọba, ẹjọba o, ẹjọba titi.
Call: Ninu rẹ o
Response: Ninu rẹ ni ipa wa o
Ninu rẹ ni gbogbo agbara ngbe
Ẹni ti ko mọn o ni n fi o sere
Eni o majanaku
Lape mori n Kan firio
Emi mọn ọ oo
Ọba mimọ
Emi mọn ọ o
Akirisore.
2ce
Call: Emi mọn ọ o, oba mimọ.
Response: Emi mọn ọ o, akirisore.
Call: Iwọ ti o pọ lagbara ti o pọ ni aanu
Response:  Emi mọn ọ o, akirisore
Call: Oun fi ounjẹ fun awon to bẹru rẹ lojojumọ
Response: Emi mọn ọ o, akirisore
Call: Talio dabi oluwa to oun gbe nibi giga julo
Response: Emi mọn ọ o, akirisore
Call: Emi mọn iṣẹ rẹ, baba
Response: Emi mọn ọ o, akirisore
(Percussion)
Jesu!
Lead: Jesu o, Ọlọrun ọmọ, iwo ma loriki kan o, ajara otitọ ni ọ, ọdọ aguntan baba
Call: Salutarevultus ni wọn njẹ l’ede Latin
Response: Itumọ ni saviour
All: Wiwa rẹ gba gbogbo awọn to bẹru iku, wiwa rẹ dawọn ni de, oosọ wọn dọmọ, etutu ẹsẹ t’Aroni n ṣe lọdọọdun o, n’iwọ ṣe lẹẹkan ṣoṣo.
 Back to Chorus : Ẹjọba, ẹjọba, ẹjọba o, ẹjọba titi.
(Repeat chorus any time the lead sings)
Lead 1: Ẹni to’n ṣe ori fun gbogbo ijọba ati gbogbo agbara pata, enikan ṣoṣo to ni aiku ton gbenu imọlẹ ti akolee sunmọn iwọ ti o pa iku rẹ tiosi mun iye ati aidibaje wa si imọlẹ nipa ihinrere.
Lead2:  Iwọ ni eni ti n bẹ ti osi tiwa ti osi n bọwa, Jesu kristi ẹlẹri olootọ, akọbi ninu awọn oku n’iwọ nṣe iwọ ṣa lalasẹ awọn ọba aye, ẹjọba.
Lead3: Olori alufa mimọ, iwọ ni ailẹgan aileeri, ti aya sọtọ kuro ninu ẹlẹsẹ o, ti asi gbega ju awọn ọrun lọ, ẹjọba.
Lead 3: Iwọ ti o joko lọwọ ọtun baba l’oke, itẹ ọla ninu awọn ọrun o, sebiwo lalarinaa majẹmu titun, ninu rẹ loun gbogbo nbẹ.
Lead 4: Olori alufa tiko nilo lati wẹra rẹ mọn koto wẹni
Olori alufa ti ko le ṣai bawa kẹdun, iwọ ti o san Idiyele igbala gbogbo wa, kọkọrọ iku ati ipo oku ọwọ rẹ ni n bẹ.
Lead 5: Olukọni ọmọ Dafidi o, aworan Ọlọrun akọbi gbogbo ẹda pata, ninu rẹ loun gbogbo duro ṣọkan, ninu rẹ o loun gbogbo nbẹ.
Lead 6: Itansan ogo Ọlọrun o, ọpa alade Ododo ni ọpa alade Ijọba rẹ, iwọ too ti ipa iku pa ẹni toni agbara iku run, ọmọ alade alafia lorukọ rẹ!
Call: Ninu rẹ o
Response: Ninu rẹ ni iye wa o
Ninu rẹ ni isọdọmọ ngbe
Iwo ni ikurẹ nṣe ifilọlẹ majẹmu titun
Ẹni tọ baba wa
nipasẹ rẹ, yoo ye o.
(Percussion…….)
Ẹmimimọ!
Lead: Ẹmimimọ oo, ọdọ rẹ lo pari si, ẹkẹta igbimọ, ẹmi Olodumare, ẹmi toun tọni sọna otitọ gbogbo ti kii sọ tara rẹ, ẹmi tọmọ ṣe leri fun wa, lati maa bawa gbé, ẹmi toun tọni sọna otitọ gbogbo ti kii sọ tara rẹ, ẹmi tọmọ ṣe leri fun wa, lati maa bawa gbé.
Back to Chorus : Ẹjọba, ẹjọba, ẹjọba o, ẹjọba titi.
Ẹjọba, ẹjọba, ẹjọba o, ẹjọba titi.
(Repeat chorus any time the lead sings)
Lead 1: Iwọ ti oun jẹri wipe ọmọ Ọlọrun lawa n ṣe, edidi onigbagbo gbogbo, ẹri ini wa, iwọ gangan leleri ipin o, ẹmimimọ, iwo ni ẹmi ayeraye.
Lead 2: Iwọ ti oun fi irora ti ako lee fi ẹnu sọ bẹbẹ fun wa, ẹmi toun gbenu onigbagbo gbogbo, ẹmi otitọ, olufihan ohungbogbo, ẹmi iye orukọ rẹ niyẹn.
Lead 3. Iwọ to jẹ ẹri ọkan fun gbogbo agbaye, ijanu ọmọ lẹyin kristi olupilẹsẹ iwe mimọ, orukọ rẹ lolutunu, orukọ rẹ lolutọni.
Lead 4: Olurannileti ohungbogbo, ẹmi isọdọmọ ati ti ifihan, iwọ gan lẹmi ọlọrun alaye ti ko lee ku o, iwọ gan lẹmi ọgbọn at’oye.
Lead 5: Iwọ lẹmi toun fi oye ye araye ni ti ẹsẹ, niti ododo ati niti Idajọ, emi ore-ọfẹ ni ọ o, ṣebi’wọ loluroni lagbara, ẹjọba.
Lead 6: Awọn griiki n pe ọ ni parakletos ede mi n pe ọ ni oluranlowo, ẹni toun wo inu ọkan wo ni ọ, alagbawi ni ọ, ẹmi otitọ ati ododo.
All: Ninu rẹ ni itoni wa o
Ninu rẹ ni ifihan ngbe
Iwo ni ẹlẹrii to daju
Pọmọ lọrun lawanṣe
Ẹnibanio oti loungbogbo.
Ẹnibanio oti loungbogbo.
Ninu rẹ ni itoni wa o
Ninu rẹ ni ifihan ngbe
Iwo ni ẹlẹrii to daju
Pomo lọrun lawanṣe
Ẹnibanio oti loungbogbo
Ẹnibanio oti loungbogbo.
(Percussion)
Call: Ẹni bani ọ, oti lohungbogbo
Res: Ẹni bani ọ,  oti loungbogbo
Call: Ko s’ẹni to le tọ Jesu l’oluwa o, bikose nipasẹ rẹ.
Res: Ẹni bani ọ, oti loungbogbo.
Call: Ifedefọ, isọtẹlẹ, imọẹmiyatọ gbogbo ẹ pata, ọwọ rẹ ni n bẹ.
Res: Ẹni bani ọ,  oti loungbogbo.
Call: Iṣẹ iyanu ni ṣiṣe, ọrọ ọgbọn ọrọ ìmọ gbogbo ẹbun toku, iwọ loni wọn.
Res: Ẹni bani ọ,  oti loungbogbo.

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *